Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ẹjọ́ Fa Igi lé Èsì Ìbò Abẹ́lé Ẹgbẹ́ PDP Ní Ìpínlẹ̀ Ògùn

0 246

Ilé ẹjọ́ gíga tí ó fi Abeokuta  se ibùjòkó ti fa igi lé  èsì ìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ òsèlú P.D.P ní ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó sì tún dá àjọ elétò ìdìbò ní ọwọ́ kọ́ láti má se àfihàn ọnarébù Ladi Adebutu  gẹ́gẹ́ bíi olùdíje fún ipò gómìnà lábẹ́ òsèlú alábùradà.

 

Nínú ìdájọ́ rẹ̀, adájọ́ O.O. Oguntoyinbo, pàsẹ fún ẹgbẹ́ náà láti se àgbékalẹ̀ ìdìbò mínràn láàrin ọjọ́ mẹ́rìnlá.

 

Adájọ́ náà gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lórí pé, yíyan àwọn tí ó kó ipa nínú ètò abẹ́lé náà kò bá ìlànà òfin mu, léyìí tí ó sì pèpè fún dídá èsì ìbò náà sí igbó láti le è fi ìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button