Rọ́síà yóò nawọ́ ìrànwọ́ sí àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn ní Mariupol ní Ukiréínì ní ọjọ́ ajé, Mikhail Mizintsev, olórí Ilé-iṣẹ́ Ìṣàkóso Ààbò Orílẹ̀-èdè Rọ́síà ló sọ èyí di mímọ̀.
Ile-iṣẹ Aabo orilẹ-ede Rọsia sọ ninu alaye kan pe, “ Awọn ara ilu ti o to aadoje ẹgbẹrun, pẹlu awọn ajeji mẹrinle-lọgọsan lati awọn orilẹ-ede mẹfa, ni o wa ninu igbekun lọwọlọwọ bayii ni orilẹ-ede naa.
Awọn ọmọ-ogun Rọsia ati awọn ẹya Donetsk yoo kede ‘ijọba ipalọlọ pipẹ’ ati ṣiṣe iṣeduro akiyesi rẹ lati agogo mẹsan aabọ owurọ orilẹ-ede Mọsiko.
Rọsia n duro de idahun Kiev si awọn igbese ti o dabaa yii titi di agogo marun owurọ akoko agbegbe naa ni ọjọ aiku,iyẹn gẹgẹ bi oṣiṣẹ naa ṣe ṣalaye.
Leave a Reply