Aarẹ orilẹ ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti balẹ si Paris ti o jẹ olu -ilu orilẹ ede France, lọsan ọjọ Isẹgun fun irinajo ọjọ kan lati jẹ́ alajo pataki fun aarẹ orilẹ ede France, Emmanuel Macron ni Palais de l’Élysée, ki aarẹ Buhari to tẹsiwaju fun ipade apero ọlọjọ mẹta to da lori eto alaafia , ni eyi ti too bẹrẹ ni ọjọ kọkanla , ti yoo si pari ni ọjọ kẹtala osu kọkanla , ọdun 2021( November 11-13, 2021).
Baalu aarẹ Buhari balẹ si papa ọkọ ofurufu ti Le Bourget ni deede aago mẹta ku isẹju mẹẹdogun (2.45pm).
Lasiko ti aarẹ yoo fi wa ni orilẹ ede France, aarẹ Buhari yoo se ipade pẹlu aarẹ orilẹ ede France lati jọ jiroro lori awọn nnkan to yoo jọ se awọn orilẹ ede mejeeji ni anfaani paapaa julọ, nipa eto idagbasoke lori ọrọ̀ ajé ,eto aabo , eto ẹkọ, eto ilera ati ọna lati gbokun ti ajakalẹ arun COVID-19.
Ti o ba di ọjọBọ aarẹ Buhari yoo maa darapọ mọ awọn akẹgbẹ rẹ lati orilẹ ede miran , awọn ile-isẹ ti kii se ti ijọba, awọn ile-isẹ aladaani ni Grande Halle de La Villette fun eto apero.
Lara awọn ti yoo wa nibi ipade apero ọhun ni aarẹ Macron, igbakeji aarẹ orilẹ ede Amerika Kamala, ati Sheikh Hasina, ti o jẹ asoju ijọba ti orilẹ ede People’s Republic of Bangladesh.
Tolulope
Leave a Reply