Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Yan Olùdámọ̀ràn Pataki Láti Ṣojú Ẹkùn Ìjọba Àpapọ̀ Àti Alága Ìgbìmọ̀ Ìrìn-àjò Hajj

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti bú ọwọ́ lù ìyànsípò Dare Adeleke gẹ́gẹ́ bíi Olùdámọ̀ràn pàtàkì tí yóò máa ṣojú Ẹkùn Ìjọba Àpapọ̀, nígbà tó yan Alhaji Hashim Atere gẹ́gẹ́ bíi Alága Ìrìn-àjò Hajj ní Ìpínlẹ̀ Òyó. Gẹ́gẹ́ bi àtẹ̀jáde tí…

Ètò Ààbò: Makinde Pèsè Ọgọ́rùn-ún (100) Ọkọ̀ Ìpàráàro Fún Àwọn Òṣìṣẹ́ Elétò Ààbò Ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti pèsè Ọgọ́rùn-ùn ọkọ̀ ìpàráàro fún àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò, nígbà tó ṣèlérí láti kún wọn lọ́wọ́ lórí akitiyan wọn láti rí dájú wí pé ètò ààbò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Gómìnà lo sọ èyí di mímọ̀…

Ìṣèjọba Mi Kòní Tẹ̀tì Láti Máa Gbé Ìgbésẹ̀ Fún Ìṣerere Àwọn Èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ – Makinde

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti tẹnu mọ pé ìṣèjọba òun kòní tẹ̀tì láti máa gbé ìgbésẹ̀ fún iserere àti àṣeyọrí ọjọ́ ọ̀la àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Bákan náà ni Gómìnà ṣèlérí láti mọ lórí ìpìlẹ̀ eléyìí tí àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ti fi…

Ẹ Má Sọ Ọgbà Ilé Ẹkọ Di Ibojì Òkú – Àjọ SUBEB Ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Kìlọ̀

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti rawọ ẹbẹ sí àwọn adari ilé ìjósìn Kristiẹni kan to ba ilé ẹ̀kọ́ Alakọbẹrẹ St. Paul, ni agbègbè Odo-Ona ni ìlú Ìbàdàn láti dẹ́kun lilo ilẹ̀ ilé ẹkọ náà fún ibojì òkú. Ẹni tíì ṣe alága Àjọ to n rí sí ìpèsè ẹkọ kárí…

Ẹnikẹni Tó Bá Tapa Si Òfin Àyíká Yóò San Ẹgbẹ̀rún Mẹ́wàá Náírà Owó Ìtanràn

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kéde rẹ̀ pé ìjìyà wà fún gbogbo ẹni tó bá tápà sí òfin tó ní ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àyíká láti san ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá naira (N10,000) tàbí kó fi oṣù kan gbáko ṣe iṣẹ́ àgbègbè. Kọmísánnà fún ọ̀rọ̀ àyíká àti ohun Alumọni ni…

Ilé Aṣòfin Èkó fọwọ́ sí ìṣúná owó ọdún 2024 oní N2.268T

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó tí fọwọ́ sí àbádofin ètò ìṣúná owó ọdún 2024 oní Tírílíọ́nù méjì lé Bílíọ́nu lọ́nà igba lé ní-ọgbọ̀n dín mẹ́ta àti mílíọ̀nù lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún náírà lé díẹ̀ (N2.268T) fún Ìpínlẹ̀ Èkó Ètò ìṣúná owó ọdún…

Makinde Kéde Ọjọ́ Mẹ́ta Láti Bọ̀wọ̀ Fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ondo Tó Papòdà

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ẹni tíì ṣe igbákejì alága ìgbìmọ̀ àwọn gómìnà,Seyi Makinde ti kéde ọjọ́ mẹ́ta láti ṣọ̀fọ̀ olóògbé Arákùnrin Rótìmí Akeredolu tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ àwọn Gómìnà Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn àti gómìnà Ìpínlẹ̀ Ondo nígbà ayé…
button