Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra, Ọ̀jọ̀gbọ́n Chukwuma Soludo, tí ṣàpèjúwe àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Àgùnbánirọ̀ tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NYSC) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábáṣiṣẹpọ̀ pàtàkì nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti tí àwọn ọ̀dọ́, bí ìpínlẹ̀ náà ṣe ń gbàlejò àwọn àgùnbánirọ̀ tuntun NYSC tí ọdún 2026.
Ayẹyẹ ìṣíṣẹ́ náà wáyé ní àgọ́ ìtọ́sọ́nà fún àwọn àgùnbánirọ̀ ní ‘NYSC Unity Permanent’ tí Nnamdi Azikiwe ní Umuawulu/Mbaukwu, ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Awka South, níbi tí wọ́n ti búra fún nǹkan bí ẹgbẹ́run kán àbọ̀ (1,500) lẹ́yìn tí wọ́n búra láti sìn Orílẹ̀-èdè Bàbá wọn.

Adájọ́ Àgbà ti Ìpínlẹ̀ Anambra, Adájọ́ O.M. Anyachebelu, tí Adájọ́ A.O. Okuma ṣojú fún ni ó ṣe ìbúra náà.
Comments are closed.