Ààrẹ Tinubu Dáwọ̀ọ́ Ìdùnnú Pẹ̀lú Gómìnà Tẹ́lẹ̀rí Fayẹmi Níbi Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí Ọgọ́ta Ọdún
Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti dunnú pẹ̀lú gómìnà Ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀rí, Kayọde Fayẹmi níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún rẹ̀, ó sàpèjúwe rẹ gẹ́gẹ́ bí olùfarajì, olóòótọ́ tí ó ń lo ìgbé ayé rẹ̀ fún ìgbáyégbádùn ọmọnìyàn
Nínú ìfọ̀rọ̀léde rẹ tí ó wáyé ní ọjọ́ Àìkú, Ààrẹ Tinubu gbósùbà fún Fayẹmi látàrí iṣẹ́ ribiribi tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bi gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀rí àti fun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lápapọ̀ àtipé ó se takuntakun fún ìsàfirinlẹ̀ ìjọba tiwa-n-tiwa tí ó wáyé ní ọdún 1999
Ó lu Fayẹmi lọ́gọ ẹnu fún àtìlẹyin tí ó se ati akitiyan rẹ síwájú, lásìkò ìpolongo ìbò, lásìkò ìdìbò sí ipò ààrẹ èyí tí ó mú kí òun jáwé olúborí nínú ìdìbò gbogbogbòò tí ó wáyé ní ọdún 2023
Ààrẹ wa gbàdúrà ẹ̀mí gígùn àti àlàáfíà tí ó péye fún gómìnà tẹ́lẹ̀rí náà