Ọ̀gá Àgbà Àjọ Ọlọ́pàá ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Olukayọde Adeolu Ẹgbetokun ti yan Godwin Ndidi Aghaulor gẹ́gẹ́ bí adarí àjọ náà, èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọ́ọ́fìsì àpapọ̀ àjọ náà tí ó wà ní Ukpo, Ìjọba ìbílẹ̀ Dunukofia, ìpínlẹ̀ Anambra. Ọwọ́jà ìsàkóso ‘rẹ̀ yóò kó Ìpínlẹ̀ Enugu àti Anambra Papọ̀
Ìyànsípò Aghaulor wáyé lẹ́yìn ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ Tony Adejoh Olofu ẹni tí ó wà ní ipò ìsàkóso náà tẹ́lẹ̀rí
Lẹ́yìn ìgbàlejò tí ó wáyé, ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun náà se àyẹ̀wò àwọn ohun èlò kí ó tó padà sí ọ́ọ́fìsì rẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.
Leave a Reply