Ìrètí wà pé Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu yóò gbéra Láti ìlú Abuja lọ sí Berlin, Germany ní ọjọ́ Àbámẹ́ta láti kópa nínú àpérò ọrọ̀ ajé èyí tí Olaf Scholz se agbátẹrù rẹ̀, tí yóò wáyé ní ogúnjọ́ osù kẹrìnlá, ọdún 2023
Agbẹnusọ fún Ààrẹ, Ajuri Ngalele sọ pé, Aarẹ yóò pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ l’àgbáyé láti jíròrò lórí ọ̀nà àti mú ìgbòòrò bá ètò ọrọ̀ ajé ní àgbáyé
Ngalele sọ pé ìgbésẹ̀ náà wà ní ìbámu pẹ̀lú ìpinu Ààrẹ láti mú ìdàgbàsókè bá ọ̀rọ̀ Agbára, Òwò, Ohun Amáyédẹrùn, Ìmọ̀ Ìgbàlódé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Leave a Reply