Mínísítà tí ó wà fún ìpèsè Ilé àti Ìdàgbàsókè Àgbègbè, Ahmed Musa Dangiwa ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wá ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìsòro tí ó ń kojú ìpèsè ilé papàá jùlọ ìsòro àti wàhálà láti rí ilẹ̀ fún ilé kíkọ́.
Mínísítà sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń se ìpàdé pẹ̀lú alága ìgbìmọ̀ ìsàtúnṣe ilẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Peter O. Adeniyi àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, Ó sàlàyé pé ètò ti parí láti wá ọ̀nà àbáyọ bí ilẹ̀ ìkọ́lé yóò se wà fún lílò ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Dangiwa jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹyìn ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu fún àseyọrí ìgbìmọ̀ náà, Ó wá lùwọ́n lọ́gọ ẹnu fún iṣẹ́ ribiribi ti wọn se.
Leave a Reply