Take a fresh look at your lifestyle.

Wọ́n ti rọ àwọn obìnrin láti ní ìgboyà, ìfojúsùn rere àti ìwà rere fún ipò aṣíwájú

0 194

Wọn ti rọ awọn ọdọbinrin ati awọn obinrin lati ni ifojusun rere, igboya ati iwa rere gegẹ bi ipilẹ fun iṣẹ aṣiwaju rere.

Awọn akikanju obinrin lorilẹ-ede Naijiria lo sọrọ iyanju yii ninu Ipade Ijiroro awọn Olóye Aṣiwaju, ti wọn fi bu ọla awọn akikanju obinrin mẹta ni orilẹ-ede Naijiria; Aṣoju orilẹ-ede (Dokita) Tokunbọ Awọlọwọ-Dosunmu, Aṣoju orilẹ-ede Hadiza Mustapha ati Aṣoju orilẹ-ede Adenikẹ Ukinga ni gbọngan CVL ni agbegbe Victoria Island ni Ipinlẹ Eko lỌjọru, Wednesday.

Ibẹ ni awọn akin obinrin yii ti fi imọran, ọrọ iṣiti ari iriri wọn ṣe ọrọ iyanju fun awọn akopa ninu ipade ijiroro naa paapaa fun awọn obinrin ti wọn yoo fi le maa wa ni ipo aṣiwaju.

Aṣoju orilẹ-ede (Dokita) Tokunbọ Awolọwọ-Dosunmu, ti o jẹ Aṣoju orilẹ-ede Naijiria tẹlẹ si orilẹ-ede Netherland, ti o jẹ ọmọ ilu-mọọ-ka Aṣiwaju, Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, o ni iriri oun nigba ti oun wa ni ipo aṣoju orilẹ-ede Naijiria ni orilẹ-ede Netherland fun oun ni ọpọlọpọ anfani lati fi gbe igbe aye rere.

Dokita Tokunbọ Awolọwọ-Dosunmu ṣapejuwe ayẹyẹ imọriri yii gẹgẹ bi eyi ti o ṣe pataki gẹgẹ bi ipo oun bi aṣoju orilẹ-ede yii nigba naa.

Nigba ti Alaga Ile-iṣẹ Iwe-iroyin ‘African Newspapers of Nigeria Plc’ naa n sọrọ, o ni, ipo oun gẹgẹ bi aṣoju orilẹ-ede yii ni Orilẹ-ede Netherland fun oun ni anfani nla lati tubọ gbe ogo orilẹ-ede Naijiria ga pẹlu aṣa orilẹ-ede yii lagbaaye. O nI:

“Mo mọ pe, mo ni nnkan lati ṣe, idi niyi ti mo fi farajin lati tun ogo orilẹ-ede Naijiria ṣe. Ọlọrun si ṣeun, ọdun 2000 ni ayẹyẹ ogoji ọdun ominira orilẹ-ede Naijiria bọ si, mo wa lo anfani eyi lati ṣe ayẹyẹ eto ọlọsẹ kan; bi ijiroro ọrọ-aje, ayẹyẹ iṣafihan aṣa nibi ti awọn olorin wa bi King Sunny Ade, ti wa kọrin, bakan naa ni ile-iṣẹ nnkan aṣa Nike Gallery naa ṣe afihan awọn nnkan aṣa wa, ati awọn eto miiran.”

“Bo ti lẹ ṣe pe, oju baba mi, Oloye Awolọwọ ni ọgọọrọ eniyan n wo mọ mi lara, bi ẹni pe, emi funra mi o da nnkan ṣe, paapaa ti mo tun kawe gboye gẹgẹ bi onimọ-iṣegun oyinbo, emi naa ti wa mọ pe, mo gbọdọ daabo bo orukọ naa, mo si sa gbogbo ipa mi. Lati igba ti mo si ti kuro ni ipo aṣoju orilẹ-ede naa, gbogbo iṣẹ ti mo ṣe ni mo le fọwọ sọya pe, wọn ni ipa rere nipa imọ, ati ti akitiyan ti mo fi ṣe wọn.”

Dọkita Tokunbọ sọ pe, ni gbogbo asiko ti oun fi jẹ aṣoju orilẹ-ede naa, o fun oun lanfani lati fọwọ sowọpọ pẹlu awọn aṣoju orilẹ-ede miiran ti wọn jẹ obinrin, ki wọn le gbe ogo wọn ga.

Lara awọn ti wọn tun fun ni ẹbun idanilọla ni Aṣoju orilẹ-ede Adenikẹ Ukonga, ti o jẹ aṣoju orilẹ-ede Naijiria tẹlẹ si orilẹ-ede Jamaica, ẹni ti o fi igbagbọ rẹ mulẹ pe, bi wọn ba ṣe korioya fun awọn ọdọ obinrin wọn yoo le ni igboya lati gba iṣẹ aṣoju ni ilẹ okeere.

Aṣoju orilẹ-ede Ukonga wa gba awọn ọdọ ode oni niyanju lati ni ifojusun fun iṣẹ ti wọn ba yan laayo, ki wọn si ni igboya pẹlu iwa ọmọluabi ninu ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe. O ni:

“Ki wọn ṣiṣẹ wọn bi o ba ṣe yẹ. Ki wọn ma maa ṣaroye pe, nitori pe wọn jẹ obinrin ki wọn maa gba aaye ti ko yẹ lẹnu iṣẹ, bíi mo gbe ọmọ mi lọ si ile-iwe, ‘hospital’. Gbogbo eyi maa n bi ọkunrin ninu. Amọ bi o ba ṣiṣẹ rẹ bi iṣẹ, bi o ba ti ẹ gba aaye pe, o fẹ gbe ọmọ ẹ lọ sibi kan, wọn a mọ pe, tootọ ni”

Ẹni kẹta ti wọn tun bu ọla fun ninu ayẹyẹ naa ni Aṣoju orilẹ-ede Hadiza Mustapha ti o jẹ aṣoju orilẹ-ede Naijria tẹlẹ si orilẹ-ede Cameroon. O rọ awọn obinrin lati tun awọn ọna ti wọn fi n ṣe nnkan ṣe, niwọn ti awọn ilana ṣiṣe nnkan wọn ko laṣeyọri.

O tẹnu mo igbesẹ fifọwọsowọpọ pẹlu awọn ọkunrin lọna akọtun lati le ni aṣeyọri ninu awọn erongba wọn. Bakan naa ni o rọ awọn obinrin ti o wa ni ipo alaṣẹ lati lo ipo wọn lọna ti yoo fi ogo rere lelẹ.

Nigba ti Oludari/Oludasilẹ gbọngan imọriri awọn Olori, iyẹn ‘Centre for Values in Leadership’, Ọjọgbọn Pat Utomi sọrọ, o ṣalaye pe, awọn mọ riri awọn akikanju obinrin mẹtẹẹta naa lawọn fi bu ọla fun wọn bayii, ati lati le jẹ ki awọn ọdọ obinrin naa mọ pe, ko sibi ti awọn ko le de nile aye.

Lara awọn akikanju to fọrọ jomitooro ọrọ nibi ijiroro naa ni Asoju orilẹ-ede Maria Oyeyinka Laoṣe, Asoju orilẹ-ede Gladys Modupẹọla Quist-Adebiyi, Ọmọwe Abiọla Salami, ati atọkun eto, Ọmọtọla Adeyanju. Wọn rọ awọn obinrin lati ja fun ẹtọ wọn, ki wọn mu igberu ba imọ wọn, ki wọn ni igbagbọ ninu ara wọn, ki wọn si ṣamulo anfani to ba wa si arọwọto wọn.

Lara awọn eto to wayẹ ninu ayẹyẹ ibu-ọla funni naa ni fifi ami ibọlafunni fun awọn akikanju obinrin mẹtẹẹta naa; lẹyin eyi ni wọn ge akara oyinbo lati fi pọn wọn le, wọn si fun wọn ni iwe ti wọn pe, akọle rẹ ni ‘Iṣẹ Atilẹyin Akin Obinrin’ (People Performing Woman’s Companion).

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button