Ilé Aṣòfin Èkó fọwọ́ sí àwọn alákoso ìlú mẹ́ẹ̀dógún ninu méjìdínlógún tí Gómìnà fi ránṣẹ́ sí wọn lẹ́ẹ̀kejì.
Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari wọn Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti fọwọ si awọn alakoso –agba ilu mẹẹdogun ninu mejidinlogun ninu ipele orukọ keji ti Gomina Babajide Sabwo-Olu fi ranṣẹ si Ile Aṣofin naa .
Eleyii waye lẹyin ti Ọlọpaa Ile Aṣofin naa, Aṣofin Mojeed Fatai, ti o tun jẹ Alaga Igbimọ Tẹẹkoto fun ṣiṣe ayẹwo awọn eniyan naa ni kikun, tẹ́ abajade iwadii wọn siwaju Ile Aṣofin naa
Ninu ipade ijiroro Ile Aṣofin naa labẹ Oludari Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa, awọn aṣofin naa kò gba Onimọ-ẹrọ Ọlalere Oduṣọtẹ ati Ọgbẹni Samuel Egube wọle.
Bakan naa, Ile tun sun fifi ọwọ si Ọgbẹni Tọlani Sule Akibu titi di ọjọ miiran.
Aṣofin Ọbasa gboriyin fun iṣẹ takuntakun igbimọ tẹẹkoto naa lati ṣe ayẹwo kikun lori awọn to fẹ gba ipo ilu naa.
Lara awọn ti Ile Aṣofin naa gba wọle ni:
Ọmọwe Afọlabi Abiọdun Tajudeen
Ọgbẹni Oluwaṣeun Oriyọmi Ọṣiyẹmi
Ọjọgbọn Akinọla Emmanuel Abayomi
Ọmọwe Oluwarotimi Omotola Fashola
Arabinrin Fọlashade Kaosarat Ambrose-Medem
Arabinrin Akinyẹmi Bankọle Ajigbọtafẹ
Arabinrin Bọlaji Celicia Dada
Arabinrin Barakat Akande Bakare
Ọgbẹni Olugbenga Ọmọtọsho
Ọgbẹni Moṣọpẹfoluwa George
Ọmọwe Yekini Nurudeen Agbaje
Ọmọwe Olumide Oluyinka
Ọgbẹni Abayọmi Samson Oluyọmi
Ọmọwe Iyabọde Oyeyẹmi Ayọọla
Aṣofin Ṣọla Shakirudeen Giwa.
Leave a Reply