Take a fresh look at your lifestyle.

Akọ̀wé-àgbà Ilé Aṣòfin Èkó rọ àjọ FRSC láti túbọ̀ mójú tó ṣíṣọ́ ojú òpópónà

0 169

Akọwe-agba Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ rọ awọn ẹṣọ oju ọna marosẹ ijọba apapọ, FRSC lati tubọ mu igberu ba amojuto wọn loju awọn opopona.

Amofin Ọnafẹkọ sọrọ iṣiti yii nigba ti olori ẹṣọ FRSC ẹka ti Ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babatunde Farinloye ṣe abẹwo si i ni Ile Aṣofin naa. O wa gbe oṣuba o kare fun ajọ FRSC fun iṣẹ ẹṣọ wọn ati bi wọn ṣe moju to irinkerindo ọkọ loju awọn opopona yii ti ki i fi si ijamba ọkọ to bẹẹ.

Akọwe-agba yii tun bẹ olori ẹka FRSC ti ipinlẹ yii lati gbe aroye awọn olugbe Ipinlẹ Eko yẹwo nipa bi awọn ẹṣọ wọn ṣe maa n dunkooko mọ wọn loju ọna, paapaa bi wọn ṣe n gba owo lọwọ wọn. O woye pe, ojuṣe gbogii to yẹ ko jẹ iṣẹ awọn ẹṣọ yii ni lati pese aabo fun awọn ọlọkọ.

O tun mu wa gẹgẹ bi aba lati ṣe agbekalẹ eto ẹkọ ati ilanilọyẹ lati tubọ fun awọn awakọ ni idanilẹkọọ bi a ṣe n lo awọn opopona. O ni:

“Laisi aniani ajọ FRSC si n ṣe ojuṣe wọn, mo si gbori yin fun yin fun eyi, ṣugbọn sibẹ orilẹ-ede Naijiria si wa lara awọn orilẹ-ede ti ijamba ọkọ ti n ṣẹlẹ ju lọ lagbaaye. Bakan naa ẹsun nipa bi awọn ẹṣọ yii ṣe n dunkooko mọ awọn olugbe Ipinlẹ Eko n pọ, inu wa a dun bi ẹ ba wa nnkan ṣe si eyi. Bakan naa ni ẹ nilo lati fun awọn awakọ ni ilanlọyẹ to tọ nipa awọn ilana oju popo. Ki awọn ẹṣọ oju popo gbogbo si fi ti ọmọniyan ṣe ninu ojuṣe wọn”

O wa fi mulẹ pe, Ile Aṣofin Ipinlẹ Eko yoo fọwọ sowọpọ pẹlu Ajọ FRSC.

Saaju eyi, Olori ẹka ẹṣọ FRSC yii beere fun atilẹyin Ile Aṣofin naa lori iwa awọn ọmọ ganfe to n da wọn laamu laarin ọna marosẹ Eko si Ibadan; iwa wiwa ọkọ tako ofin oju popo; wiwa ọkọ tì si ibi ti ko tọ ati tita ọja loju popo.

Ọgbẹni Farinloye ṣalaye pe, iru awọn iwa wọnyin n ṣe idiwọ fun lilọ-bibọ ọkọ loju popo. O wa beere fun ṣiṣe ofin ti yoo le wa ojutu si awọn iṣoro wọnyi. O ni:

“Maa rọ Ile Igbimọ Aṣofin yii lati ṣe agekalẹ awọn ofin ti yoo le koju awọn iwa buruku awọn ọmọ ganfe loju ọna marossẹ Eko si Ibadan, ọja tita loju popo ati iwakuwa awọn ọlọkọ ero. Bakan naa ni a rọ ajọ KAI lati ri daju pe, ko si ọja tita loju popo gẹgẹ bo ṣe wa labẹ ofin. Bi a ba ṣe gbogbo awọn nnkan wọnyi,awọn opopona wa yoo le ja geerege.

Ninu idahun re si bi awọn ẹṣọ FRSC ṣe n gba owo lọwọ awọn ọlọkọ, o ni owo ti awọn n gba lọwọ awọn ọlọkọ ko to nnkan bi a ba fi we eyi ti awọn ajọ ẹṣọ oju popo miiran n gba.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button