Ilé Ẹjọ́ tí ó ń gbọ́ ìfẹ̀hónúhàn lórí ìdìbò gbogbogbòò tí ó kọjá ti sún ìdájọ́ síwájú lórí ẹjọ́ tí olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú PDP, Atiku Abubakar pè tako ìjáwé olúborí Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu.
Adájọ́ Haruna Tsamani ni o fi ọrọ lede, lẹ́yìn ìgbà tí Atiku parí fífi ìdí àwọn ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ fún ilé ẹjọ́.
Igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀rí àti ẹgbẹ́ PDP tako àbájáde ìbò pẹ̀lú ẹ̀sùn wípé màgò-mágó wáyé nínú èsì ìdìbò náà. Wọ́n wá pàrọwà sí ilé ẹjọ́ láti fagilé èsì ìbò náà, kí àtúndì ìbò míràn sì wáyé.
Leave a Reply