Ile-ẹjọ giga Ijọba Apapọ ni ilu Eko lọjọru (Friday) to kọja, dá Aṣofin Mosunmọla Ṣangodara ti Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko lare ẹsun ayederu iwe ẹri ti wọn fi kan an.
Aṣofin Ṣangodara ti o n ṣoju ẹkun idibo Surulere keji ninu ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ni Adajọ Oweibo ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ ilu Eko fi mulẹ ninu idajọ rẹ pe ẹsun ti wọn fi kan naa ko lẹsẹ nlẹ.
Ninu ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ naa, Adajọ naa ni o fi han pe, ko si ododo ninu ẹsun ti olupẹjọ, Ọgbẹni Ọlasunkanmi Kazeem Shittu fi kan Aṣofin naa, pe awọn iwe ẹri rẹ ko duro deedee, ati pe Ạṣofin Ṣangodara lanfani lati du ipo aṣofin ti yoo ṣoju fun ẹkun Surulere ninu Ile Aṣofin naa labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Nigba ti o n fi idunnu han fun iṣẹgun rẹ, Aṣofin Ṣangodara ri ajaṣẹgun rẹ gẹgẹ bi ọwọ agbara Ọlọrun ati atilẹyin awọn eniyan.
Bakan naa ni o tun dupẹ lọwọ awọn eniyan ẹkun Surulere keji fun atilẹyin alailẹgbẹ wọn si i.
Ni pataki, o fi ẹmi imoore rẹ han si Olori ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ti o tun n dupo aare orilẹ-ede Naijiria lạbẹ ẹgbẹ oṣelu naa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, Aṣofin Fẹmi Gbajabiamila, Oludari Ile Igbimọ Aṣojuṣofin orilẹ-ede yii ati Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti i ṣe Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Eko fun atilẹyin wọn ni gbogbo igba to n koju ẹjọ yii.
Aṣofin Ṣangodara fẹmi imoore han si olupẹjọ naa ati awọn alatilẹyin rẹ fun ọna ti wọn gbe ọna naa gba, eyi ti wọn fẹsẹ ofin tọ. Bakan naa lo rọ wọn lati jọ fọwọ sowọ pọ lati tubọ mu ilọsiwaju ba ẹkun idibo Surulere keji.
O tun ṣe ileri ati fi itẹriba sin awọn eniyan ẹkun idibo Surulere keji ati Ipinlẹ Eko lapapọ ni asiko yii, laini foju pẹnikan rẹ.
Ba a ba ranti, wọn fi ẹsun ayederu iwe ẹri kan Aṣofin Mosunmọla Ṣangodara ninu akitiyan rẹ lati du ipo aṣofin fun ẹkun idibo Surulere keji ninu Ile Igbimọ Ipinlẹ Eko labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).
Leave a Reply