Take a fresh look at your lifestyle.

Ọmọ Ogún Nàìjíríà Dá Ìkọlù Àwọn Ajínigbé Ní Kaduna Dúró

56

Àwọn ọmọ ogún tí FANSAN YAMMA tí dá ìkọlù àwọn ajínigbé dúró, wọ́n sì ti pa ẹni tí wọ́n fura sí pé ó jẹ́ oníwà ipá lẹ́yìn ìkọlù àwọn ajínigbé ní agbègbè gbogbogbò Maraban Rido ní ìpínlẹ̀ Kaduna.

‎ Ìgbésẹ̀ àṣeyọrí náà tẹ̀lé ìpè tí wọ́n gbà ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kejìlélógún (22) oṣù kíní ọdún 2026, tí wọ́n tá wọn ní olobo tí àwọn ajínigbé náà láti abúlé Anguwan Fulan ní àárín agbègbè Rido.

‎Gẹ́gẹ́ bí àlàyé ìṣẹ́ naa, àwọn ọmọ ogun yára lọ sí agbègbè náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n sì ìkọlù wọn kíákíá ní àfojúsùn láti rí àwọn ọ̀daràn tó sá lọ.

‎ Nígbà tí wọ́n kàn sí wọn, àwọn ọmọ ogun náà fi agbára ìbọn tó ga jù kojú àwọn ajínigbé náà, wọ́n sì fipá mú wọn láti sá padà pẹ̀lú ìdààmú pẹ̀lú ọgbẹ́ ìbọn, nígbà tí wọ́n sì pa ọ̀kan lára àwọn ajínigbé náà nígbà ìjà wọn.

Comments are closed.

button