Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Kenya William Ruto ti gúnlẹ̀ sí ìlú Beijing ní alẹ́ ọjọ́ Ìsẹ́gun fún àbẹ̀wò lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rin sí Orílẹ̀-èdè China
Àbẹ̀wò náà ni ó jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹta irú rẹ̀ sí China nígbà tí ó ti gun orí àlééfà
Ìrìnàjò ìsàbẹ̀wò náà wáyé pẹ̀lú ìpè láti ọwọ́ Ààrẹ Orílẹ̀-èdè China, Xi Jinping tí ìrètí wà pé yóò mú ìbásepọ̀ tí ó múná dóko wáyé láàrin Orílẹ̀-èdè méjéèjì náà ní ẹka òwò, ìgbòkè-gbodò àti ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé