Ẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan Ìṣòwò Asia àti Pacific (APEC) tí ṣé ìkìlọ̀ ní Ọjọ́bọ̀ pé àwọn ọjà òkèèrè ní àgbègbè náà kì yóò dàgbà ní ọdún yìí láàrín ìbẹrẹ tí àwọn Owó-orí-òwò tí America.
Àwọn aṣojú ìṣòwò America àti China náà pàdé ní ẹgbẹ kàn níbí àpéjọ fún àwọn ìjíròrò ìlọsíwájú lórí àwọn ìdíyelé ìṣòwò.

Awọn ọmọ ẹgbẹ mọkànlèlogún tí APEC náà daba àwọn ọjà òkèèrè ní àgbègbè náà yóò gunke sí pẹ̀lú ìdá 0.4% ní ọdún yii, ní àkàwé pẹ̀lú ìdá 5.7% ní ọdún tó kọjá, ní ìtúpalẹ̀ pẹ̀lú ìrírí àwọn ìṣòwò aṣa àgbègbè náà ní ìpàdé àwọn Mínísítà ìṣòwò tí 2025 tí wọ́n ṣé ní erékùṣù Jeju tí South Korea.
Ẹgbẹ́ náà tún gé àsọtẹlẹ ìdàgbàsókè ètò-ọrọ àjé àgbègbè rẹ̀ fún ọdún yìí sí 2.6% láti 3.3% tẹ́lẹ̀.

Àpéjọ APEC ní àwọn Mínísítà ìṣòwò àti àwọn aṣojú láti àwọn orílẹ̀-èdè ọmọ ẹgbẹ́ Japan, Canada, Mexico àti Russia.
Comments are closed.