Ààrẹ Orílẹ̀-èdè South Africa, Cyril Ramaphosa àti Ààrẹ Orílẹ̀-èdè America Donald Trump tí ṣètò láti pàdé ní Ilè Ìjọba America ní ọsẹ tí n bọ̀ lẹ́yìn àwọn ẹsùn tí Trump pé wọ́n ń ṣé ẹlẹyamẹya láàrín àwon dúdú áti fúnfún ní Orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ dúdú èyí tí Ramaphosa kọ̀.
Ìpàdé náà tí Ìjọba South Africa kéde ní wọ́n ṣètò sí fún ọjọ́ kọkànlélogún, Oṣù Kàrún, lẹ́yìn tí Ààrẹ America náà yóò gbá àlejò àwọn aráàlú South Africa fúnfún mọkàndínlọgọ́ta (59) bí alasala ní ọjọ́ Ajé yìí.
Ààrẹ Trump sọ pé ètò gbígbà ilẹ̀ lọwọ́ àwọn àgbẹ̀ fúnfún ní Orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ náà ṣàfihàn inúnibíni àti ẹlẹyamẹya fún wọn nínú ilú wọ́n.
Ààrẹ South Africa kọ́ àwọn ẹsùn náà o sí sọ pé àwọn aláwọ̀ fúnfún ní orílẹ̀-èdè dúdú ní a kó yà sọtọ fún inúnibíni.
Comments are closed.