Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin ,Ọ̀gbẹ́ni Abbas Tajudeen ti dunnú pẹ̀lú àwọn òsìṣẹ́ ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà látàrí ìdàgbàsókè aláìlẹ́gbẹ́ tí wọ́n mú bá Orílẹ̀-èdè
Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni rẹ̀ fún àyájọ́ àwọn Òsìṣẹ́ èyí tí ó máa ń wáyé ní ọjọ́ kíní osù karùn-ún ọdọọdún, Abbas sọ pé Ilé Asòfin yóò tẹ̀síwájú nínú ìmọ rírì ipa àwọn òsìṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alátìlẹyìn fún ìtẹ̀síwájú
Ó gbósùbà fún ẹgbẹ́ òsìṣẹ́ NLC Àti TUC fún ipa wọn nínú ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé àti ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè, àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn pẹ̀lú ìsèjọba Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu látàrí ìpèsè àwọn ohun amáyédẹrùn lásìkò tí Orílẹ̀-èdè ń dojúkọ ìpèníjà ọlọ́kan-ò-jọ̀kan