Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Kẹ́dùn Pẹ̀lú Iran Látàrí Ìjàmbá Ìbúgbàmù

136

 

Ìjọba àpapọ̀ orílè-èdè yìí ti kẹ́dùn pẹlu orílè-èdè Iran látàrí ìjàmbá Ìbúgbàmù tó pa méjìdínlọ́gbọ̀n ènìyàn tó sì jẹ kí ènìyàn tó le lẹ́gbẹ̀rin farapa .

 

Mínísita ilẹ̀ òkèèrè, Ambasedọ̀ Yusuf Tuggar, ló fi ìkíni ìjọba yìí ránṣẹ tí wọ́n gbé jáde lọ́jọ́ Àìkú láti ọdọ agbẹnusọ Mínísirì, Kimiebi Ebienfa.

 

Ìbúgbàmù náà ṣẹlẹ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní Shahid Rajaee Port, tó wà ní gúsù Iran lẹ́gbẹ̀ẹ́ Strait of Hormuz.

Tuggar sọ pé, ” Ìjọba kẹ́dùn pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Iran, Nàìjíríà wà pẹ̀lú wọn ní àkókò tó le koko fún wọn yìí, Oluwa a wà pẹlu ìdílé tó sọ ẹ̀mí àwọn èniyàn rẹ̀ nù nínú ìṣẹlẹ burúkú yìí.

” Èrò wà àti ádùrá rere wa, wà pẹ̀lú àwọn tó lùgbàdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti ẹbí àti orílẹ̀-èdè Iran lápapọ̀.”

 

 

 

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Comments are closed.

button