Àjọ Gencos ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti palrọwà sí ìjọba àpapọ̀ àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ láti wá ojútùú sí ìsòro gbésè iná mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n pèsè àti èyí tí àwọn oníbàáárà rẹ̀ lò
Alága Àjọ Gencos, ajagunfẹ̀yìntì Sani Bello ni ó pe ìpè náà, ó sì sèkìlọ̀ pé gbèsè tí ó tó tírílíọ̀nù mẹ́rin tí àwọn oníbàáárà rẹ̀ jẹ le è fa okùnkùn biribiri tí kò bá sí ọ̀nà àbáyọ
Ó tẹ̀síwájú pé lẹ́yìn gbèsè owó tí wọ́n jẹ àjọ náà oníran-ìran ìpèníjà ní àjọ náà tún ń dojú kọ tí ó le è mú ìfàsẹ́yìn bá ìdàgbàsókè ìpèsè iná mọ̀nàmọ́ná
Ó wá la àlàkalẹ̀ ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú ìgbésẹ̀ ní kíákíá èyí tí yóò mú kí àjọ náà le è tẹ̀síwájú nínú ojúse rẹ̀