Bí awuye-wuye, ìdààmú dààbo àti wàhálà ti ó n sẹlẹ̀ ní South Sudan kò se tí ì fi ara rọ, ni àjọ UN náà kò kùnà nínú ojúse rẹ̀ láti rí i dájú pé alaafia jọba ní àgbègbè náà tí àwọn ọmọ ogun àjọ náà sì wà ní ojú ni alákàn fi ń sọ́rí ní gbogbo ìgbà
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ogun lé n dé ni ó wà ní inúfo-àyàfo ní gbogbo ìgbà látàrí bí wàhálà se ń sẹlẹ̀ káàkiri Orílẹ̀-èdè láàrin àwọn ikọ̀ méjì tí ọ̀rọ̀ kàn, tí awuye-wuye àti àìgbọ́ra-ẹni-yé ẹgbẹ́ òsèlú sì ń wáyé ní olú ìlú Orilẹ-ede naa
Kò sí ìfọ̀kànbalẹ̀ ní South Sudan lásìkò yíì, sùgbọ́n akitiyan ń lọ lọ́wọ́ láti dá àlàáfíà padà sí Orílẹ̀-èdè náà