Ìjàm̀bá iná tí ó wáyé ní àgbègbè Iwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀-èdè South Koria ti ń tẹ̀síwájú níbi tí ènìyàn mẹ́rìnlélógún ti pàdánù ẹ̀mí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó pàdánù ẹ̀mí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà wà ní ẹni ọgọ́ta sí aadọrin ọdún, níbiti àwọn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n míràn ti fi arapa yán-na-yàn-na, tí àwọn méjìlá sì wà ní apakán ayé- apákan ọ̀run. Ìsẹ̀lẹ̀ láabi náà tí sọ àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún dí aláìnílé látàrí sísá àsálà fún ẹ̀mí wọn
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá ni ó bá ìsẹ̀lẹ̀ láabi náà lọ tí ilé ìjọsìn ìsẹ̀m̀báyé Gounsa náà sì wà lára wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé akitiyan wáyé láti kó àwọn ohun èlò kúrò níbẹ̀, síbẹ̀ nǹkan bàjẹ́ tayọ àlà
Ìsẹ̀lẹ̀ iná náà bẹ̀rẹ̀ ni Sancheong, ni ọsan ọjọ Ẹti, léyìí tí ọwọ́jà rẹ̀ sì dé Uiseong.