Ìgbáyégbádùn Ọmọnìyàn Se Pàtàkì Lásìkol Yìí Àti Ní Ọjọ́ Iwájú – Arábìnrin Francisca Obialor
Alámójútó àpapọ̀ fún ìgbáyégbádùn ọmọnìyàn ẹka tí gúsù Ilà oòrùn, èyí tí ó kó ìpínlẹ̀ Anambra, Enugu Imo, Abia, Ebonyi, sínú, arábìnrin Francisca Obialor ni ó sàlàyé pàtàkì ẹ̀tọ́ olùrajà àti ìgbáyégbádùn ọmọnìyàn níbi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lásìkò ayẹyẹ ẹ̀tọ́ olùrajà lágbàyéé, èyí tí ó wáyé ní ìlú Awka, Ìpínlẹ̀ Anambra
Nínú ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nu-wò tí ó wáyé pẹ̀lú ilé Akéde tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó tẹ́ pẹpẹ pàtàkì àyájọ́ náà, àtipé o ́wà fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀tọ́ àti ojúse àwọn olùrajà jákè-jádò gbogbo àgbáyé
Ó tẹ̀síwájú pé ìgbé ayé àlàáfíà yóò wáyé pẹ̀lú síse àmójútò àgbègbè, ìmọ́tótó, ìtẹ́pẹpẹ ẹ̀tọ́ àti ojúṣe àwọn olùrajà èyí tí yóò mú ìdàgbàsókè àti àǹfàní wáyé ní ọjọ́ iwájú