Mínísítà Fún Ètò Ìnáwó àti Gómínà Báńkì Àpapọ̀ àwọn Orílẹ̀-èdè àjọ ECOWAS ni ó ti pè fún ìdásílẹ̀ owó kan ṣoṣo fún àjọ náà èyí tí yóò se àmúgbóòrò ètò ọrọ̀ ajé àti ìgbáyégbádùn jákè-jádò Iwọ̀ Òrùn Áfíríkà
Ìpè náà wáyé níbi ìpàdé àpérò ẹlẹ́ẹ̀kẹkọ̀nlá irú rẹ̀ tí ó wáyé ní ìlú Abuja, olú ìlú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ìpàdé náà sàgbéyẹ̀wò àbájáde àjọ náà lórí ètò ọrọ̀ ajé àti àwọn agbékalẹ̀ míràn tí ó se pàtàkì. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé náà, minisita Ètò Ìnáwó ti Orílẹ̀-èdè Naijiria, Adebayo Ọlawale Ẹdun fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé, pípèsè owó kan ṣoṣo yóò se ìrànlọ́wọ́ fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé àti ìbásepọ̀ tí ó múná dóko fún awọn Orílẹ̀-èdè Iwọ̀ Òrùn Afirika