Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Bola Ahmed Tinubu, ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, kéde ìbẹ̀rẹ̀ ìdíje eré àwọn Ọlọ́pàá (Biennial Police Game BIPOGA) ẹlẹẹkẹrinla tí wọ́n pé ní “Oluyole 2024”.


Nígbà tó ń kéde iṣide ètò náà ní Lekan Salami Sport Complex, ní àgbègbè Adamasingba nílùú Ibadan, ní Ìpínlẹ̀ Oyo, Ààrẹ Tinubu, ẹní tó jẹ́ àlejò pàtàkì, woyé pé eré ìdárayá àwọn Ọlọ́pàá Nàìjíríà tí jẹ́ ọ̀kan gbóògì látí ṣé àwáàrí àwọn ogbontarigi eléré, èyí tí Ààrẹ rò pé yóò tún ṣé bó tí ń ṣé.

Ààrẹ ẹní tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo àtí agbalejo ètò náà, Seyi Makinde ṣojú fún, rántí bí ọlọ́pàá Chioma Ajunwa ṣé gbá àmì ẹ̀yẹ góòlù fún Nàìjíríà ní Òlímpíkì Atlanta ọdún 1996.
Next Post
Comments are closed.