Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Kwara Bẹ̀rẹ̀ Kíkọ Àwọn Ilé-Ìgbọ̀nsẹ̀ Ti Ìgbàlódé Fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀

232

Ìpínlẹ̀ Kwara tí bẹ̀rẹ̀ kíkọ àwọn ilé-ìgbọ̀nsẹ̀ ìgbàlódé ní àdúgbò Alanamu, ní ìjọba ìbílẹ̀ ‘Ilorin west’ tí ìpínlẹ̀ náà.

Èyí jẹ́ lára àwọn ìgbìyànjú rẹ̀ látí dáwọ ìgbọ̀nsẹ̀ ní gbángba dúró kí àlàáfíà lè bá jọba nílu.

Ìṣẹ́ náà wà gẹ́gẹ́ bi ojúnà látí dẹkùn ìpèníjà ètò àyíká, èyí tí wọ́n yóò kọ́ sí àwọn Ọjà, ọgbà ọkọ̀ àti àwọn Ilé-ìwé.

Àwọn àgbègbè mìíràn tí ìjọba yàn fún àwọn ilé-ìgbọ̀nsẹ̀ náà ní Ajikobi, Eruda àtí àwọn àgbègbè mìíràn ní ìpínlẹ̀ náà.

Nígbà tó n sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ìdásílẹ̀ náà ní Ilorin, olú ìlú Ìpínlẹ̀ náà, Kọmíṣọ́nà fún Ọ̀rọ̀ Omí, Usman Yunusa-Lade sọ pé àwọn ilé-ìgbọ̀nsẹ̀ náà ní wọ́n pèsè látí fí ṣé ìdàgbàsókè àtí igbelarugẹ ìwà ìmọ́tótó ní àwọn ààyè náà.

Comments are closed.

button