Olùdarí Ilé-iṣẹ́ Kukah, Reverend Fr. Atta Barkindo tí ké sí àwọn ilé ìjọ́sìn látí tún jí ẹmí ìhìnrere pàdà, ṣé àgbé gá fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀, ètò-ẹ̀kọ́ àtí ìkópa nínú ètò òṣèlú látí ṣé àtìlẹ́yìn fún ìjọba tiwa-n-tiwa, àlàáfíà àti ìdàgbàsókè ní Nàìjíríà.
Barkindo ṣé ipè yìí lákókó tó ń sọ̀rọ̀ níbí ọsẹ kẹ́ta tí ìkẹ́kọ tí Ilé-ẹ̀kọ́ ‘Good Shepherd Seminary’ ní Kaduna.
Barkindo, tó tún jẹ́ Alákóso tí, ‘National Peace Committee NPC,’ sọ pé wiwá àlàáfíà àtí ìdàgbàsókè ní Nàìjíríà jẹ́ díẹ nínú ìgbìyànjú láti ṣé igbelaruge orílẹ̀-èdè, ifẹ orílẹ̀-èdè, àtí ìsọkan orílẹ̀-èdè.
Ó kẹ́dùn bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ní ìrírí oríṣiríṣi ìwà ipá àti rògbòdìyàn ṣáájú àti lẹ́yìn òmìnira rẹ̀ ní ọdún 1960.