Orílẹ̀-èdè United Arab Emirates ti parí fífi ọ̀rọ̀-jomitoro-ọ̀rọ̀ pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Congo lórí ìbásepọ̀ òwò tí ó dán mánrán, èyí tí ó jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kejì tí yóò wáyé pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè adúláwọ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ kan
Láti ọdún 2021 ní Orílẹ̀-èdè UAE ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ náà èyí tí yóò fún-un ní ànfààní láti tẹ̀síwájú nínú ìdókoòwò pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Áfíríkà
Látàrí ìgbésẹ̀ náà ní àsọyépọ̀ fi wáyé ní ọ̀ṣẹ̀ tí ó kọjá pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀, èyí tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀.