Ilé-ìgbìmọ̀ Ọmọ-ogun Nàìjíríà tí fọwọ́sí ìgbéga àwon òṣìṣẹ́ àgbà kàn sí Major General àti Brigadier General lẹsẹsẹ.
Èyí jẹ́ yọ́ látí orí ìkànnì X agbẹnusọ Ọmọ-ogun, Brigadier General Onyema Nwachuckwu ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejilelogun, Oṣù Kejìlá, Ọdún 2023.
NIGERIAN ARMY PROMOTES SENIOR OFFICERS
The Army Council has on Thursday 21 December 2023, approved the promotion of senior officers to the next ranks of Major General and Brigadier General respectively. A total of 47 Brigadier Generals have been promoted to the rank of Major… pic.twitter.com/c6rAVgHh2k
— Nigerian Army (@HQNigerianArmy) December 22, 2023
O fí hàn pé àpapọ̀ ‘Brigadier General’ mẹ́tadìnlàádọta (47) ní wọ́n gbéga sí ipò ‘Major General’, nígbà tí àwọn Colonel márúndìnlọgọ́rin (75) gbá ìgbéga sí ipò Brigadier General.
Ọgá àgbà àwọn ọmọ ogún, Lieutenant General Taoreed Lagbaja tí kí àwọn ọgá àgbà túntún tí wọ́n gbá ìgbéga àtí àwọn ẹbí wọ́n, ó wà rọ wọ́n látí ṣiṣẹ́ takuntakun síwájú sí.