Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ tó ń dárí àwọn ọmọ ogún Ojú-omí tí fọwọ́sí ìgbéga tí àwọn òṣìṣẹ́ àgbà Méjìdínlọgọ́ta (58) sí àwọn ipò orísirísi ní ilé-iṣẹ́ ogún Nàìjíríà.
Àwọn méjìdínl’ọgbọ̀n (28) ló gbá ìgbéga láti ipò Balógun (Captain) sí ‘Commodore’, nígbàtí àwọn ọgbọ̀n (30) mìíràn gbá ìgbéga láti ‘Commodore’ lọ́ sí ‘Rear Admiral’.
Gẹ́gẹ́ bí Olùdarí ìròyìn tí Ile-iṣẹ́ náà, Commodore Adedotun Ayo-Vaughan, tó wà lára àwọn òṣìṣẹ́ àgbà túntún tó gbá ìgbéga náà láti ‘Commodore’ sí ‘Rear Admiral’ ṣé sọ nínú ọrọ kàn pé àwọn tó gbá ìgbéga láti Rear Admiral náà ní; Commodores Adefemi Kayode, Kabir Mohammed, Gabriel Aligwe, Aliyu Gaya, Shehu Gombe, Godfrey Kwetishe, Robert Obeya, Musa Katagum, Kehinde Odubanjo, Pakiribo Anabraba, Suleiman Ibrahim, Olugbenga Oladipo, Haruna Zego, Adedotun Ayo-Vaughan, Mohammed Dahiru, Nnamdi Ekwom, Stephen Ibrahim, Mohammed Muye, Aniefiok Uko, Anenechukwu Ezenma, Olufemi Adeleke, Etop Ebe, Sunday Yahaya, Umaru Faruk, Michael Igwe, Ikenna Ubanni, Emmanuel Anakwe, Omotola Olukoya.
Àwọn tó gbá ìgbéga láti Commodores ní; Captains Innocent Udoudoh, Mohammed Umaru, Iliya Abdu Aiwuyor Adams-Aliu, Reginald Adoki, Abimbola Agunbiade, Christian Akokota, Chukwuma Azuike, Adegoke Ebo, Innocent Ejiofor, Tahir Ngada, Oluseyi Oladipo, Shehu Tasiu, Aliyu Umaru, Peter Yilme, Sikiru Abdulraheem, Tunde Abdulrahim, Emeka Chinaka, Effiom Ekpenyong, George Nwabunike, Akinrinsola Obisesan, Igbani Agwu, Babatunde Kuton, Ahmad Madawaki, Momoh Salihu.
Nígbàtí Joseph Ake, Captains Hassan Dogara, Olajide Babalola àtí Suleiman Idris gbá ìgbéga ifẹyinti.
Olórí ọmọ ogún Ojú-omí, Vice Admiral Emmanuel Ikechukwu Ogalla AM gbóríyìn fún gbogbo àwọn tó gbá ìgbéga náà, ó sí rọ̀ wọ́n látí tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ takuntakun bí wọ́n ṣé ń dáàbòbo Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, kí wọ́n sì ní ìgbàgbọ nínú ìsàkóso Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu GCFR.