Take a fresh look at your lifestyle.

Kò Yẹ Kí Wọ́n Fún Israel Ní Àṣẹ Látí Máa Pá Ènìyàn – Qatari Amir

0 270

Emir tí Qatar tí pé àwọn orílẹ̀-èdè Àgbáyé látí dá Israeli lọ́wọ́ kọ́ nínú ogún wọ̀n pẹ̀lú Hamas, Ó sọ pé kò yẹ kí àwọn ọmọ-ogun Israeli kàn máa pá àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Palestine lainidii nínú ogún wọ̀n pẹ̀lú Hamas.

Nínú ọrọ̀ iṣide rẹ̀ níbí àpéjọ ọdọọdún tí ìgbìmọ̀ Shura ní ọjọ́ Ìṣẹgun, Sheikh Tamim bin Hamad Al Thani tún sọ pé ìtẹ̀síwájú ogún náà léwu púpọ̀ fún àgbègbè náà.

“Á ń sọ pé ó tó,” o sọ.

Emir tẹ̀síwájú látí dẹbi iwa-ipa tí Israel wù sí àwọn aráàlú ẹgbẹ méjèèjì, ṣùgbọ́n Ó tún dá ẹbí fún Àjọ Àgbáyé fún “ ìwà olójú méjì àti àbòsi” lórí bí wọ́n ṣé ń pá àwọn ọmọ kékèké ní Palestine lọ́nà àìtọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button