Take a fresh look at your lifestyle.

China Yọ General Shangfu Gẹ́gẹ́ Bí Mínísítà Ààbò

0 275

Orílẹ̀-èdè China tí yọ General Li Shangfu kúrò gẹ́gẹ́ bí Mínísítà Ààbò ní ọjọ́ Ìṣẹgun, èyí jẹ́ ìgbà Kejì tí wọ́n yóò yọ Olùdarí àgbà ní àárín oṣù mẹ́ta, lẹyìn tí wọ́n tí yọ́ Mínísítà Ilẹ̀ òkèèrè Won Gang ní Oṣù kéje, tó tí ń fá ìbéèrè nípa ìgbésẹ̀ Ààrẹ China Xi Jinping.

Gen. Shangfu tó tí ń yẹ́ra ní ìpàdé gbángba láti bí oṣù Méjì, ní wọ́n yọ kúrò bí Mínísítà Ààbò ní ìbámu pẹ̀lú ilé ìròyìn Orílẹ̀-èdè náà.

Kò tí sí orúkọ kọọkan tí yóò rọ́pò fún Li nígbà tí wọ́n palẹmọ fún igbalejo àwọn òṣìṣẹ́ Ààbò Ilẹ̀ òkèèrè ni Àpéjọ Beijing Xiangshan ní ọjọ́ 29-31, oṣù kẹwàá ọdún 2023.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button