Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Aṣòfin Anambra Gbèrò Ìpolongo Láti Lòdì Sí Gbígbé Oògùn Olóró

0 266

Ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin tí Ìpínlẹ̀ Anambra tí gbèrò ìpolongo láti lòdì sí gbígbé oògùn olóró àti ipá búburú rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ náà.

Ilé-ìgbìmọ̀ náà fí ontẹ lú àbàdòfin náà, wọ́n sì rọ Gómìnà Chukwuma Soludo láti ṣètò bí àwọn Kọmiṣọna fún Ìlera, Àlàyé, Àwọn ọdọ, Ìṣòwò Àjé, Imọ-ẹrọ àti àwọn ilé-iṣẹ́ mìíràn tó yẹ láti bẹ̀rẹ̀ ètò ìpolongo náà.

Àbàdòfin náà ní aṣòfin tó ń ṣoju àgbègbè Njikoka Kejì, Jude Akpua gbé kalẹ̀ làkókò ìpàdé àwọn aṣòfin náà èyí tí Chidi Ibemeka tó nṣoju àgbègbè Njikoka àkọ́kọ́ ṣé àtìlẹ́yìn fún.

Olórí Ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin, Somtochukwu Udeze tó ṣé adari ìpàdé náà, tí ṣé ifilọ náà nígbà tí àwọn aṣòfin gbà pẹ̀lú ibò oùn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button