Ìjọba ìpínlẹ̀ Niger, ààrin gbùngbùn Nàìjíríà ti mú lele lórí iṣẹ́ awọn oníròyìn láti túbọ̀ máa gbé ìròyìn òtítọ́ àti ìròyìn tó ní ìtumọ̀ síta fún aráyé gbọ́.
Nínú atejade kan láti ọwọ́ akọ̀wé àgbà àwọn oníròyìn sí ìjoba, ọ̀gbẹ́ni Bologi Ibrahim, pe àkíyèsí àwọn oníròyìn láti yẹra fún ìròyìn òfegè, ìròyìn ti wọn kò ti wàdí rẹ̀ wò fínífíní nítorí pé iru re leè dá rúgúdù àti ìbẹ̀rù bojo sílẹ ní àwùjọ.
Ìjọba ìpínlẹ̀ náà tilẹ̀ ṣẹ́ ìròyìn kan tó n jà ràì-ràìn pé nǹkan ọmọkùnrin tàbí ojú ara Obìnrin kan sọnù ni laipẹ yi, wí pé Irọ́ ni kò sí òtítọ nibẹ̀. Ààbò tó péye wà ni ilé ìjọba, Minna àti káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ náà, àwọn agbófinró wà lójú iṣtẹ.
Ìjọba ti wá pàrọwà fún àwọn ará ìlú àti oníròyìn láti gbé ìròyìn òtítọ́ síta, kí wọn máṣe tan ìròyìn òfegè káàkiri, kí wọ́n sì gbájúmọ́ iṣẹ́ òòjọ́ wọn láì bẹ̀rù.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply