Alhaji Kabir Dan’lami Rimi tó jẹ́ Alága ìgbìmọ̀ adéle fún Katsina United FC tí ke sí àwọn àgbábọ́ọ̀lù àti àwọn onímọ̀ eré láti ṣé àtìlẹ́yìn fún àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ adéle túntún tí wọ́n yàn láti jẹ́ kí ẹgbẹ́ náà lè ga sí.
Rimi ṣé ipè náà ní kété lẹyìn tí Olùdarí Àwọn eré ìdárayá tí Ìpínlẹ̀ náà Abdu Bello ṣé àfihàn rẹ̀ fún àwọn àgbábọ́ọ̀lù àti àwọn òṣìṣẹ́ onímọ̀ eré ìdárayá ní kété lẹyìn ikẹkọ igbábọ́ọ̀lù irọlẹ.

Ó gbá àwọn àgbábọ́ọ̀lù náà níyànjú láti dúró ṣinṣin pẹ̀lú òye pé ìgbìmọ̀ adéle túntún náà wá láti ṣé ìrànlọ́wọ́ fún ẹgbẹ́ náà láì ṣọdẹ ẹnikẹni.
Bákannáà, ní ó rọ àwọn alatilẹyin ẹgbẹ́ láti ṣé àfihàn àtìlẹ́yìn wọ́n fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ adéle náà nípa jí jáde wá wòran ní ọjọ́ Àbámẹ́ta pẹ̀lú ẹgbẹ́ Lobi Star’s FC.
Leave a Reply