Ilé Aṣòfin Èkó gbóríyìn fún ìgbésẹ̀ àbẹ̀wò àwọn Olùdarí Ilé Aṣòfin lápá Ìwọ̀ Òòrùn Gúsù orílẹ̀-èdè Nàíjíríà sí wọn
Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko gboriyin fun igbesẹ abẹwo ti igbimọ awọn Oludari Ile Aṣofin lapa Iwọ Oorun Gusu orilẹ-ede Naijiria ṣe si Ile Igbimọ Aṣofin Ipinẹ Eko nibi ti wọn ti jiroro pẹlu Oludari Ile Aṣofin Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa lori ilọsiwaju ẹkun yii.
Ninu Ijiroro Ile Aṣofin naa lọjọ Iṣẹgun Tuesday, Olori Ọmọ Ẹgbẹ Oṣelu to pọ julọ ninu Ile, Aṣofin Noheem Adams, woye pe, eleyii fi ipa akikanju Aṣofin Ọbasa mulẹ, ẹni ti o ti jẹ Alaga tẹlẹ fun Igbimọ Awọn Oludari Ile Aṣofin Ipinlẹ orilẹ-ede Naijiria, gẹgẹ bi ẹni to ṣe e fọkan tan. O ni:
“O jẹ ohun iwuri ati nnkan ayọ lati fi han pe, iwa Oludari Ile yii, Aṣofin Ọbasa, jẹ ohun iwuri nla, eyi to n fun Ile Aṣofin yii ni iyi nla”
Igbakeji Ọlọpaa Ile, Aṣofin Setonji David naa fi idunnu rẹ han si bi awọn Oludari Ile yooku ṣe gboriyin nla fun Aṣofin Ọbasa ninu ipade wọn naa.
O ṣalaye pe, dipo ki Aṣofin Ọbasa jẹ ipe awọn eniyan lati tẹ siwaju gẹgẹ bi Alaga fun Igbimọ Awọn Oludari Ile Aṣofin Ipinlẹ lorilẹ-ede Naijiria, o pinnu lati gbe ipo naa silẹ ki ẹlomiran bẹrẹ lati ibi to ba a de.
Aṣofin Gbọlahan Yishawu sọ pe, ipade awọn Oludari ti wọn wa ṣe ni Ile Aṣofin Eko fi han pe, eniyan daradara ni Oludari Ile Aṣofin Eko, ti o ko awọn yooku mọra. O ni:
“O jẹ ohun iwuri funmi pe Aṣofin Ọbasa jẹ ọmọ Ipinlẹ Eko, ti o tun wa lati apa Iwọ-Oorun Gusu orilẹ-ede Naijiria..”
Aṣofin Abiọdun Tọbun dupẹ lọwọ awọn alejo naa fun ifọkan tan wọn ninu Aṣofin Ọbasa ati iṣẹ aṣiwaju rẹ. O wa rọ Oludari Ile naa lati tẹ siwaju ninu iṣẹ daradara naa, o si gbadura fun pe, Ọlọrun yoo sọ agbara rẹ di ọtun.
Igbakeji Olori Ọmọ Ẹgbẹ Oṣele to pọ julọ ninu Ile, Aṣofin Richard Adedamọla naa gboriyin fun iṣẹ akin Aṣofin Ọbasa ati bi awọn yooku ṣe ni igbagbọ ninu rẹ.
Bakan naa ni Aṣofin Ladi Ajọmale dupẹ lọwọ Oludari Ile naa fun awọn idanilẹkọọ ti awọn ti lanfani si labẹ rẹ.
Lẹyin gbogbo ọrọ iwuri yii ni Igbakeji Oludari Ile, Aṣofin Mojisọla Meranda ti o dari ipade ijiroro naa lorukọ Oludari Ile, paṣẹ pé ki Akọwe-agba Ile, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ ko iwe ifẹmi imoore han si Oludari Ile Aṣofin Ipinlẹ kọọkan lati apa Iwọ Oorun Gusu orilẹ-ede Naijiria ti wọn wa nibi ipade naa.
Leave a Reply