Àjọ Tí Ó Ń Mójútó Ìtọ́jú Ohun Ọ̀sìn Ti Fi Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òògùn Ráńsẹ́ Sí Ìpínlẹ̀ Niger Lójúnà Àti Dènà Àrùn Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀
Àjọ tí ó ń mójútó ìgbáyégbádùn àwọn ohun ọ̀sìn, tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Plateau ti fi òògùn àjẹsára oníkóró ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́ta sọwọ́ sí ìpínlẹ̀ Niger lójúnà àti dènà àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ èyí tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.
Alákòsóo àjọ náà, Maryam Muhammad ni ó sí aṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà nípa akitiyan àti ètò láti dènà àrùn burúkú náà.
Ó wá se ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn láti jínà sí lílo ayédèrú òògùn fún ìtọ́jú àrùn náà nítorí pé ó léwu jọjọ.
Leave a Reply