Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko Aṣofin Mudashiru Ọbasa gba alejo Ọọnirisa, Kabiyesi Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja Keji, Ọọni Ifẹ lọjọ Aje Monday.
Kabiyesi ninu ọlanla wọn wọ gbagede Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ naa ni deedee aago kan aabo, ti wọn si lo ṣe ipade pẹlu Oludari ile naa loju ese.
Kabiyesi fi gbagede ile naa silẹ ni kete ti wọn pari ipade naa saaju ipade ijiroro ile.
Oọni Ife, Ọba Ogunwusi saba maa n ṣe abẹwo si Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko
Ni ọdun 2016, Wọn gboriyin fun Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ naa fun akitiyan wọn lori gbigbe ogo ede ati aṣa Yoruba larugẹ.
Ni ọdun 2017, ẹwẹ, nigba ti wọn ṣabẹwo si ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ yii, Ọba ba Ogunwusi rọ awọn Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ kaakiri ilẹ Yoruba lati gbe ede Yoruba larugẹ. O ni:
“Inu mi dun lati wa nibi yii, paapaa bi Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ yii ṣe n fi ede Yoruba ṣe ijiroro wọn. Mo wa rọ awọn Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ yooku ni ilẹ Yoruba lati tẹle iru igbese Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko yii.
“Awọn eniyan ni awọn orilẹ-ede miiran mo riri ede Yoruba, ṣugbọn o ṣe ni laanu pe awa funra wa ko mo riri nnkan wa.
Fun idi eyi, mo ro ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko lati ba awọn Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ yooku ni ilẹ Yoruba sọrọ ki awọn naa maa lo ede Yoruba ninu ijiroro wọn. Eleyii yoo le gbe ede ati aṣa Yoruba larugẹ.”
Leave a Reply