Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti fọwọ si eto ẹyawo ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinlẹ Eko beere lati ya lọwọ ijọba apapọ nipasẹ Ile-iṣẹ ijọba apapọ fun Eto Iṣuwona, Iṣuna owo-ilu ati Iṣeto ilu, lati le ri owo pari iṣẹ akanṣe ojuna ọkọ ẹkun yii ati oju ọna marosẹ agbegbe Lekki lọ si Ẹpẹ.
Awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin naa ti wọn n ṣiṣẹ lori eto iṣuna owo ilu ọlọdọọdun ti ọdun 2022 fun Ipinlẹ Eko ni wọn pe ni ipe pajawiri lati wa jiroro lori eto ẹyawo naa ki wọn si fọwọ si i.
Nibẹ ni wọn ti fọwọ si owo naa ti iye rẹ jẹ biliọnu mẹta ati miliọnu lọna aadọta-le-lẹẹdẹgbẹrin naira (N3,750,000,000.00) fun iṣẹ akanṣe ẹkun yii, ti wọn si fọwọ si biliọnu mẹẹdogun naira (N15,000,000,000) fun pipari iṣẹ akanṣe ọna marosẹ agbegbe Lekki lọ si Ẹpẹ. Apapọ owo naa je biliọnu mejidinlogun ati miliọnu lọna aadọta-le-lẹẹdẹgbẹrin naira (N18,750,000,000.00).
Ninu ọrọ rẹ, Alaga Igbimọ to n moju to Eto Iṣuwo-na ilu ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Rotimi Olowo so pe ele-ori ẹyawo naa jẹ iko marun ninu ida ọgọrun-un pere fun ọdun meji akọkọ, lẹyin eyi ni yoo jẹ iko mẹsan-an ninu ida ọgọrun-un, ti wọn yoo si tun fi aaye ọdun meji silẹ ki wọn to maa san owo naa pada.
Ninu ọrọ tirẹ, Aṣofin Setonji David woye pe ele–ori owo naa ko pọ rara, eyi ti wọn yoo fi odiidi ọgbon ọdun san, nigba ti awọn iṣẹ idagbasoke ti wọn yoo lo owo naa fun yoo mu igberu ati idagbasoke ba ọrọ-aje ipinlẹ yii.
Aṣofin Bisi Yusuf fi kun ọrọ naa pe eleyii yoo le tete jẹ ki wọn pari gbagede idokoowo nla ti agbegbe Lekki. Bakan naa ni awọn aṣofin yooku fi ohun wọn gbe si ẹyawo naa lẹyin, eyi ti atunbotan rẹ yoo mu ọpọ anfani wa si ipinlẹ yii.
Lẹyin eyi ni Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa fọwọ si i, ti o si paṣẹ fun Adele Akọwe-agba Ile, Ọgbẹni Ọlalekan Ọnafẹkọ lati fi ẹda ipinnu ile naa sọwọ si Gomina.
Leave a Reply