Àjọ Omọ Ogun Orílẹ̀-èdè Mali ti fi ọ̀rọ̀ léde pé, àjọ náà ti rán àwọn alákatakítí mọ́kànlélógún lọ sí ọ̀run àpàpàndodo, nígbà tí ikọ̀ ọmọ ogun se ìkọlù sí ibùba wọn tí ó wà ní Sebabougou, Orílẹ̀-èdè Mali
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí àjọ náà fi léde ní ọjọ́ Ajé, Sebabougou ti wà lábẹ́ àkóso ìjọba lẹ́yìn ìgbà tí ìmọ̀ àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí ènìyàn náà ti di òtúbáńtẹ́
Ìròyìn fi yéwa pé lẹ́yìn àwọn mọ́kànlélógún tí ó pàdánù ẹ̀mí, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn burúkú náà ni ó sálọ pẹ̀lú ọgbẹ́ ọta ìbọn, tí wọ́n sì fi ibùba wọn sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ohun ìjà wọn. Àjọ ọmọ ogun ti ń gbìyànjú láti rí i dájú pé ọwọ́ tẹ àwọn tí ó sálọ náà tí wọn yóò sì fi imú kó ata òfin