Take a fresh look at your lifestyle.

Ìrìnàjò Hajj Ọdún 2024: Alákòóso Hajj Ẹka Ti Abuja Kéde Gbèdéke Ìforúkọsílẹ̀

0 144

Alákòóso Fún Ìrìnàjò lọ sí Orílẹ̀-èdè Saudi Arabi fún Ìjọsìn Hajj, ẹka ti Abuja ti mú gbèdéke ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n osù kejìlá fún ìforúkọsílẹ̀ àwọn tí ó bá gbèrò láti rin ìrìnàjọ̀ náà fún ti ọdún 2024

 

Mallam Abubakar tí ó jẹ́ alákòóso àgbà fún ètò Hajj ni ó sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó se àbẹ̀wò sí àwọn Ọba Alayé àti àwọn alénulọ́rọ̀ lórí gbèdéke ìforúkọsílẹ̀ náà

 

Evuti tẹ̀síwájú pé àjọ náà ti se ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn lórí àlàkalẹ̀ àti òfin tuntun tí ìjọba Orílẹ̀-èdè Saudi Arabia se lórí ìrìnàjò Hajj Ọdún 2024.

 

Nínú àfikún ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ó sàlàyé pé àwọn tí ó bá gbèrò láti rín ìrìnàjò náà ní láti san owó tí ó tó mílíọ̀nù mẹ́rin àbọ̀ sílẹ̀ láti fún wọn ní ànfààní ìforúkọ sílẹ̀.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button