Asòfin Ọbasá ṣe ạyẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣítí
Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Asofin Mudashiru Ọbasa ṣe ạyẹyẹ ọjọ ibi ọdún kọkànléláàdọ́ta rẹ pẹlu awọn akẹkọọ ni awọn ile-iwe loriṣiiriṣi ni agbegbe Agege ni Ipinlẹ Eko, nibi ti o ti soro iṣiti fun wọn lati gbiyanju jẹ akikanju laaye ara wọn.
Aṣofin Ọbasa wa kede iranlọwọ owo fun awọn akẹkọọ kan, ti o si sọrọ iṣiti fun wọn pe dandan ni ki wọn ṣe oriire lọjọ iwaju bi wọn ba foju si ẹkọ wọn. O ni:
“Wiwa wa sibi lonii jẹ ara mimu igberu ba igbesi aye yin nitori ẹ o maa ranti ọjọ oni, yoo si jẹ ohun iwuri fun yin lati ṣaṣeyọri.”
O sọ fun awọn ọmọ ile-iwe naa pe, wọn le mu ala ire wọn wa si imuṣẹ paapaa ninu iṣẹ ti wọn ba yan laayo nitori aaye gba wọn nibikibi. O ni:
“Ẹ le ṣe aṣeyọri ninu iṣẹ ti ẹ ba yan laayo, bi ẹ ba tẹpa mọṣẹ yin. Ẹ le di Gomina Ipinlẹ Eko tabi Aarẹ orilẹ-ede yii. Ipinlẹ Eko lonii le figa gbaga pẹlu ọpọ awọn ilu-nla ni agbaye, ohun si ni ilu-nla ti ọrọ-aje rẹ gbooro ṣikarun-un ni ilẹ Afirika, bo tilẹ ṣe pe ipinlẹ ni wa ninu orilẹ-ede kan.
“Ni bayii ẹ maa kawe yin deedee. Bi ẹ ko ba bẹrẹ si ni maa kawe yin bayii, yoo ṣoro ki o mọ yin lara nigba ti ẹ ba dagba. Ẹ gbọdọ kawe yin daradara lati fi gbaradi fun idanwo.”
Fun ẹyin obinrin, ẹ gbiyanju lati jẹ ohun iwuri fun awọn obi yin ati awujọ yin. Ẹ ma jẹ ki awọn ohun to n ṣẹlẹ lawujọ bayii ti yin si ohun ti ko yẹ.”
Bakan naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin Eko ṣe ileri pipese awọn ẹrọ ayarabiaṣa komputa fun awọn akẹkọọ ile-ẹkọ girama ‘Oyewole Secondary School’ ni Agege nibi ti Oludari naa ti jade ẹkọ girama rẹ.
Nigba ti o n ba awọn akẹkọọ naa sọrọ, Giwa ile-ẹkọ fafiti Ipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Ibiyẹmi Ọlatunji-Bello sọ pe, oun ko tilẹ nii lọkan lati kekere pe, oun yoo wa di ọjọgbọn lonii. O rọ awọn ọmọ ile-iwe naa lati jẹ ọmọ rere, ki wọn ma ṣe jẹ ki ipenija ọrọ-aje to n da ọpọ obi laamu bayii, da omi tutu si wọn lọkan, ki wọn ṣiṣẹ takuntakun fun ọjọ iwaju rere wọn. O ni:
“Ẹ gbọdọ gbiyanju lati maa fakọyọ ninu ẹkọ yin, ko si ẹni ti ko le di Giwa ile-ẹkọ giga. Ohun ti ẹ nilo ni lati fọkan jin lẹnu ẹkọ yin. Ko nii ṣe pẹlu ẹka ẹkọ ti ẹ ba yan laayo, ẹ ṣaa ṣe daradara ninu rẹ ni.”
Leave a Reply