Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Ti Pè Fún Ìwádìí Tí Ó Yanjú Lórí Ìkọlù Àwọn Jàgùdà Sí Ilé Ìfowópamọ́ Ní Ìpínlẹ̀ Benue
Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Àgbà ti késí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti se ilwádìí ìkọlù èyí tí ó wáyé ní ilé ìfowópamọ́, ní ìlú Otukpo, ìpínlẹ̀ Benue, láti ri dájú pé àwọn onísẹ́ láabi náà fi imú kó ata òfin.
Ìgbésẹ náà wáyé látàrí àbádòfin tí sẹ́nétọ̀ Abba Moro tí ó sojú Apá Gúsù ìpínlẹ̀ Benue tì síwájú ní ọjọ́ Ìsẹ́gun, èyí tí ó pè fún ìwádìí ní kíá-kíá.
Ìròyìn fi yéwa pé àwọn alọ-kólóhun- kígbe náà ta àtamọ́ra ogun tí wọ́n sí se ìkọlù sí ilé ìfowópamọ́ tí ó wà ní ìlú Otukpo, ìpínlẹ̀ Benue, ní ọjọ́ Ẹtì, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lọ.
Ó tẹ̀síwájú pé méjì nínú àwọn oníṣẹ́ láabi náà ni ó pàdánù ẹ̀mi nígbà tí wọ́n da ojú ìbọn kọ arawọn pẹ̀lú àwọn agbófinró tí àwọn tí ó kù sì fi ara gba ọta kí wọ́n tó na pápá bora.
Leave a Reply