Take a fresh look at your lifestyle.

Lórí Ọ̀rọ̀ Nnamdi Kanu, Ilé Ẹjọ́ Gíga Àpapọ̀ Yóò Fí Ìdájọ́ Léde Ní Osù Kejìlá

0 230

Ilé Ẹjọ́ Àpapọ̀ tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti kéde ọjọ́ kẹẹ̀dógún osù kejìlá gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí ìdájọ́ yóò wáyé lórí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ tí olórí ajìjàgbara fún òmìnira Biafra se sí ilé ẹjọ́ náà, èyí tí ó rọ ilé ẹjọ́ fún ìtúsílẹ̀  láti ọwọ́ ìjọba àpapọ̀.

 

Àwọn adájọ́ máàrún, èyí tí Adájọ́ Kudirat Kekere-Ẹkun darí ti se ìfiléde ní Ọjọ́bọ̀ láti dá ẹjọ́ náà ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún osù kejìlá lẹ́yìn ìgbà tí ẹ̀gbẹ́ méjéèjì tí fí àwíjàre léde níwájú ilé ẹjọ́.

 

Ní báyìí, ọjọ́ kẹẹ̀dógún osù kejìlá ni ìdájọ́ yóò wáyé ní ilé ẹjọ́ àpapọ̀.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button