Take a fresh look at your lifestyle.

Ikú Mohbad: Àwọn Afẹ̀hónù-hàn wọ Gbàgede Ilé Aṣofin Èkó

0 201

Ikọ awọn ara Eko kan lạbẹ akori ti wọn pe ni, “Idajọ Ododo Fun Mohbad” tí gbajugbaja oṣere, Iyabọ Ojo ṣaaju wọn, gbe ifehonu-han wọn wọ gbagede Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko lỌjọRu, Wednesday, lati beere pe, ki awọn aṣofin Ile yii gbe igbesẹ lori iwadii iku ojiji to pa gbajugbaja onkọrin ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn, Ireoluwa Ọladimeji Alọba ti ọpọ mọ si Mohbad.

Nigba ti wọn n ba awọn aṣofin kan lati inu Ile Aṣofin naa ti wọn gbẹnu Oludari Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa, sọrọ, Iyabọ Ojo ni, “ki i ṣe tuntun nipa iroyin iku Ọgbẹni  Ireoluwa Ọladimeji Alọba ti ọpọ mọ si Mohbad mọ, eleyii ti iku rẹ ru ọpọ eniyan loju.”

“Mohbad ti fi ọpọ fọnran tẹlẹ sita nipa bi awọn ile-iṣẹ agborin-jade to fi silẹ lati da tiẹ silẹ, ṣe n dun kooko mọ. Bo tilẹ ṣe pe, Alakoso-agba Ile-iṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori iku naa, sibẹ a n fẹ idajọ ododo.”

Igbakeji Olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ ju lọ ninu Ile Aṣofin Eko, Aṣofin Adedamọla Kasunmu dupẹ lọwọ awọn afẹhonuhan naa fun ẹmi suuru ti wọn fi ṣe eto ifẹhona-han naa, o wa ṣe ileri pe, gbogbo ibeere wọn ni awọn yoo gbe siwaju Oludari Ile. O ni:

“Ijiroro Ile waye lanaa, lara awọn ohun ti a jiroro le lori ni ọmọ ti ara ifun rẹ kan di awati, ṣugbọn o ṣeni laanu pe, ana yẹn naa lọmọ naa gbẹmi mi. Bakan naa la sọrọ nipa iku Mohbad naa. Mo fẹ fi da yin loju pe, ofin yoo ṣe iṣẹ rẹ. Sibẹ, ẹ jẹ ka duro de abajade iwadii Ọga Ọlọpaa, ki a to mọ igbesẹ to kan.”

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin naa to wa nibẹ ni Aṣofin Sylvester Ogunkelu, Aṣofin Ajani Owolabi ati Aṣofin Rasheed Shabi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button