Take a fresh look at your lifestyle.

Níbi Ìjàm̀bá Kírènì Tí Ó Já: Òsìṣẹ́ Mẹ́rìndínlógún Pàdánù Ẹ̀mí Ní Orílẹ̀-èdè India

0 248

Kò dín ní ènìyàn mẹ́rìndínlógún tí ó pàdánù ẹ̀mí, tí àwọn míràn sì farapa yán-na-yàn-na níbi ìjàm̀bá kírènì tí ó já níbi tí wọ́n ti ń kọ́ afárá, ní apá iwọ̀ oòrùn India, ìpínlẹ̀ Maharashtra.

 

Fán-án-rán kan sàfihàn ibùsiṣé náa,̀ níbití kírènì ti já, lẹ́bàá afara Shahapur, tí ó tó ọgọ́rin kìlómítà sí Mumbai, tí ó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

 

Àwọn olùdóòlà ẹ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní wàrà-ǹ sesà, tí wọ́n sì ti kó òkú àwọn ènìyàn mẹ́rìndínlógún jáde.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button