Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara AbdulRahaman AbdulRasaq ti kí igbákejì rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Kayọde Alabi kú oríire fún ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún, ó gbàdúrà ìgbé ayé rere, àti àlàáfíà fún-un.
Gómìnà sàpèjúwe ọlọ́jọ́ ìbí náà gẹ́gẹ́ bí olóòtọ́ọ́, aláànúú ènìyàn, ó wá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìfarajì àti ipa ribiribi rẹ̀ fún àseyọrí ìsèjọba wọn láti ọdún 2019.
Gómìnà gbàdúrà kí ọlọ́run jẹ́ kí Kayọde Alabi se ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láyé.
Leave a Reply