Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó Se Àlàkalẹ̀ Ètò Láti Mú Ìdẹ̀kùn Bá Ará Ìlú Látàrí yíyọ Ìrànwọ́ Orí Epo
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti se àwọn àlàkalẹ̀ ètò lójúnà àti mú ìrọ̀rùn ba ará ìlú látàrí yíyọ ìrànwọ́ orí epo
Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀gbẹ́ni Babajide Sanwo-olu bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ọ́ọ́fìsì rẹ̀, ní Ikẹja, níbi ti o ti kede mímú àdíkù ba owó ìgbòkè-gbodò ọkọ̀ ní ipinlẹ naa èyí ti yóò bẹ̀rẹ̀ ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kejì osù kẹjọ ọdun 2023.
Sanwo-Olu salaye pe àwọn ohun ìgbáyégbádùn náà yóò jẹ ìdẹ̀kùn fun ara ilu títí tí ìjọba àpapọ̀ yóò fi pari ètò tirẹ̀ fun ìpèsè ohun ìdẹ̀kùn látàrí yíyọ ìrànwọ́ orí epo.
Leave a Reply