Take a fresh look at your lifestyle.

Àṣeyorí Ètò Ìdìbò Gbogboogbò 2023 ní í ṣe pẹ̀lú ìpalẹ̀mọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tí a ṣe- Àjọ INEC

0 329

Ajọ Eleto Idibo orilẹ-ede Naijiria, INEC fi mulẹ pe awọn ti gbaradi fun eto idibo Gbogboogbo ọdun 2023 ṣaaju aṣeyọri eto idibo Aarẹ ati Ile Igbimọ Aṣofin Apapọ to n lọ lọwọ.

Ile-iṣẹ Ajọ INEC ni Ipinlẹ Ekiti sọ pe gbogbo eto lo to ṣaaju asiko yii, ti gbogbo awọn ohun eelo tete tẹ awọn lọwọ lati olu ile-iṣẹ Ajọ INEC ti awọn si tete ko wọn kaakiri awọn ibudo idibo ni awọn agbegbe ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Ipinlẹ Ekiti.

Olori Ẹka Ilanilọyẹ ati Ipolongo Ibo ni Ile-iṣẹ Ajọ INEC ni Ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Temitọpẹ Akanmu ṣalaye pe gbogbo ohun eelo idibo, eleyii to jẹ ẹlẹgẹ ati eyi ti ki i ṣe tẹlẹgẹ ni wọn ti tete ko de lati nnkan bi ọjọ meji ṣaaju ọjọ ibo. O ni

“Eyii ni a ṣe lati fi tete le palẹmọ fun eto idibo yii, ti o jẹ ki a le tete ṣi awọn ibudo idibo lọjọ idibo”

Ọgbẹni Akanmu ṣalaye pe ajọ INEC ti mura silẹ fun eto aabo to nipọn fun awọn ara ilu ṣaaju eto idibo naa. O ni Ajọ INEC ti ṣamulo eto idanilẹkọọ lati ṣe ilanilọyẹ fun awọn ara ilu lati le jẹ ki alaafia jọba ni asiko eto idibo yii. O ni gbogbo eto lo ti waye ti alaafia yoo fi wa ṣaaju asiko ibo yii.

Ninu ọrọ rẹ gbogbo awọn ondibo to forukọsilẹ lati dibo ni Ipinlẹ Ekiti jẹ ẹgbẹrun lọna mejidinlọgọrin-le-ẹẹdẹgbẹrun ati ẹẹdẹgbẹrun-le-metalelogun (988,923), ti awọn ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin le mẹrinlelọgbon ati ẹẹdẹgbẹrin-le-aadọta-din-mẹrin (734,756) ondibo ti gba Kaadi Idibo Alalopẹ wọn ninu wọn lati igba ti  eto idibo Gomina ti waye ni Ipinlẹ naa lọdun 2022.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button